Know Your Language
Preserving language, culture & identity. Promoting culture through words and tradition
Learn. Speak. Connect.
Ni ile Yoruba, won maa n fun omo ni oruko ni ojo kejo ti a bi tabi won si aye. Yoruba gbagbọ pe awọn orukọ ni agbara tobẹẹ ti wọn ni ipa lori igbesi aye, iwuwasi, iduroṣinṣin ati aṣeyọri ọmọ nitori re niyoruba e n a pa ni owe pe "ile l'a a n wo k'a too s'omo lo'ruko" . Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ Yorùbá ni wọ́n ń fún ní orúkọ tí ó ju ẹyọ kan lọ lọ́jọ́ tí wọ́n ń ṣe isomo l'orúkọ wọn, idi abajọ ni pe awọn ọmọ tuntun gba orukọ lati ọdọ baba, iya wọn; awon obi ti o bi awon iya ati baba won ati awọn ibatan miiran ti o sunmọ won.
Ni opolopo igba, isori meji ni orukọ Yoruba
Orukọ Amuwaye tabi Abiso.
Apẹẹrẹ oruko amuwaye/ amutorunwa ni:
Ige: Omo ti o mu ese jade nigbati a bi.
Oke:
Ajayi: Omo ti o ko oju si ile nigbati a bi.
Ojo/Aina: Omo ti o gbe ibi ko orun nigbati a bi. Aina ni Obirin, Okunrin si n je Ojo
Dada Omo ti irun ori re ta koko nigbati iya re bi.
Ilori: Omo ti iya re ko se nkan osu rara ki iya re to lo'yun re.
Taiyewo/ Taiwo: Toaiyewo omo ti o koko jade ninu iya won ninu awon ibeji
Kehinde: Ake'yindegbe'gbon/ Ake'hindegbe'gbon, yoruba gbagbo pe keyinde ni egbon taiyewo gege bi oruko yi ti fihan.
Oni: Omo ti o ke pupopupo, ti o ko lati dake ekun ni si sun nigbati a bi.
Abidemi: Omo ti iya re bi ni'gbati baba wa ni irinajo.
Idowu: Omo ti iya bi le'yin ibeji.
Apẹẹrẹ oruko abiso ni:
Ayowale, Ayanwole, Adeboga, Akinyale, Awonuga, Morenikeji, Ogunsola, Ojedele Fadipe, Eegundoyin, Omiyele ati bebe lo.
Ise Lo'gun Ise lati owo Oloogbe Ojogbon J.F Odunjo
ISE LO'GUN ISE!
Ise lo'gun ise
Mura si se re, ore mi
Ise la fi n de’ni giga
Bi a ko ba re’ni fe’yin ti
Bi ole la a n ri
Bi a ko ba re’ni gbe’kele
A te ra mo’se ni
Iya re le lowo lowo
Baba re le le’sin le’kan
Ti o ba gbo’jule won
O te tan ni mo so fun o
Ohun ti a ko ba ji’ya fun
Se kii n le to’jo
Ohun ti a ba fa’ra si’se fun
Ni n pe lo’wo eni
Apa la'ra igunpa ni iyekan
B'aiye ba fe o loni
Ti o ba lo’wo lo’wo, won a tun fe o lola
Abi ki o wa ni’po atata
Aiye a ye o si te’rin te’rin
Je ki o de’ni ti n ra’go
Ko ri bi aiye ti n yin mu si o
Eko si tun se’ni do’ga
Mura ki o ko dara-dara
Iya n be fo'mo ti ko gbon
Ekun n be fo’mo ti o n sa kiri
Mafo’wuro se’re ore mi
Mura si’se ojo n lo.
Itumo ni Ede Geesi (Translation in English language)
The antidote to poverty is hard work
So work hard, Dear Friend
Success only comes through hard work
When there is no one to rely on
It’s like we are lazy
When there is no one to trust
We focus on our work
Your mum may be rich
Your dad may own a thousand and one horses
If you rely on their wealth
You are sinking fast to your shame
Whatever we do not work for
Will not last
It is what we strive for
That endures
Your arms and elbows are your family
If you are feted by society today
If you are still rich, they will fete you tomorrow as well
When you hold an esteemed position
You will be regarded with great joy
Just wait and become a pauper
And see how you will be treated with disdain
Education can take you to the top
Study hard
The unwise will surely regret their folly
The outcome for lack of planning is tears
Don’t waste your early years
Make hay while the sun shines.
Click here to claim your Sponsored Listing.
Category
Website
Address
Dubai