FIBAN LAGOS

FIBAN LAGOS

Share

FREELANCE AND INDEPENDENT BROADCASTERS' ASSOCIATION OF NIGERIA

17/12/2021

Ìròyìn Àwòko
Ọjọ́ Ẹtì,ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù Ọpẹ́,ọdún 2021.

Ètò ààbò tí ó mẹ́hẹ ni orílẹ̀ èdè Nàìjíríà lè gbégidínà ètò ìbò ní ọdún 2023-jega.

Ìjọba orílẹ̀ èdè Nàìjíríà yóò gba owó ìrìn-àjò ni ojúnà Èkó sí Ìbàdàn, Afárá Niger kejì àti àwọn ojúnà ìmíràn.

Gómìnà Sanwóolú kí Ààrẹ Buhari kú oríire àyájọ́ ọjọ́ ìbí ọdún mọ́kàndínlọ́gọ́rin rẹ̀.

Ìpànìyàn ní Kaduna/Katsina: Àwọn àjọ sọ fún ìjọba àpapọ̀ kí ó kéde ǹkan kò fararọ lẹ́nu ètò ààbò.

Masari rọ àwọn ènìyàn kì wọn dẹ́kun àríyànjiyàn ṣùgbọ́n kí wọ́n gbógun ti ètò ààbò tí ó mẹ́hẹ.

Àjọ adájọ́ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà gbégidínà ìgbéga àwọn adájọ́ àgbà márùn-ún nítorí ẹjọ́ èké.

Àwọn orílẹ̀ èdè àti àjọ ilẹ̀ òkèèrè rọ Buhari kí ó máa dójúti àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà

Ìgbìmọ̀ aṣojúṣòfin fajúro sí bí àwọn ènìyàn ṣe ń ta afẹ́fẹ́ ìdáná lọ́nà tí kò bá òfin mu.

Oyinlọlá sọ pé ìyàlẹ́nu ni bí Àkàndé ṣe ń bẹnu àtẹ́ sí Ọbásanjọ́.

Ìpínlẹ̀ Kogi níílò ọgbọ́n bílíọ́ọ̀ọ̀nù náírà láti san owó owó àjẹmọ́nú- Gómìnà Bello.

Gómìnà Bayelsa àti Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ànọ́ ṣí iṣẹ́ àkànṣe àtúnṣe ojúnà Ọ̀yọ́ sí Ìsẹ́yìn.

Àjọ tí ó ń mójútó ètò ìgbòkègbodò Mọ́tò lọ alùpùpù àádọ́jọ ni Olú Ìlú Abuja.

Owó àkànṣe iṣẹ́ àgbẹ̀ mílíọ̀nù ẹ̀ẹ́dẹ́ gbẹ̀ta àti méjìdínlógójì dọ́là AFDB yóò dín ìṣẹ́ àti ọ̀wọ́n gógó owó ilẹ̀ òkèèrè kù ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.

Àwọn ará ọjà Balógun faraya bí ọjà Balógun ṣe jóná.

Wọn bá òkú àrẹ̀mọ àti obìnrin kan ní ìhòòhò nínú Mọ́tò.

Orílẹ̀ èdè UK bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ètò fífún ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ní ìwé ìwọ̀lú padà.

Àjọ NPFL, Eyimba àti Rangers rí onígbọ̀wọ́

Arsenal fi ìyà jẹ West Ham.

Ndidi, Iheanacho gbé ọ̀ṣùbà káre sí Aguero tí ó fẹ̀hìntì lójijì.

Christian Eriksen dágbére fún àwọn agbábọ́ọ̀lù Inter Milan.

Ọlọ́run kò ní tìwá jábọ́.

Àyìnlá Omi.

14/12/2021

Méjì náà ni!.....

👉 |fẹ́ràn👍| kọ-ọ̀rọ̀✍️| pín-in⚡

14/12/2021

Ará Òwu Kìí Rán'ró, Àwíì-Mẹ́nu-Kúrò Ni T'Òwu...........

👉 |fẹ́ràn👍| kọ-ọ̀rọ̀✍️| pín-in⚡

14/12/2021

Ẹ Jẹ́ Ká Jọọ Gbé Òńkà Yìí Yẹ̀wò🤗

👉 |fẹ́ràn👍| kọ-ọ̀rọ̀✍️| pín-in⚡

Want your business to be the top-listed Media Company in Lagos?
Click here to claim your Sponsored Listing.

Telephone

Address


Lagos